BRIGADIER MOBOLAJI JOHNSON
MOBỌLAJI JOHNSON, ỌKUNRIN LỌ! Ọkan pataki ninu awọn ọmọ Yoruba ti jade laye o: Ọgagun Mobọlaji Johnson ni. Fun awọn ti ko ba mọ, Ọgagun Johnson ni gomina akọkọ ti ipinlẹ Eko ni, nitori gbara ti wọn da ipinlẹ naa silẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu karun-un ọdun 1967, oun ni wọn yan bii gomina ologun.
Oye to jẹ nigba naa ni Mejọ (Major), ko ti i di ọọfisa onirawọ rẹpẹtẹ. Ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn (31) pere ni lọjọ naa lọhun-un, iyẹn lawọn kan ṣe n pe e ni 'gomina kekere.' Ni 1936 ni wọn bii niluu Eko, lọjọ kẹsan-an, oṣu keji ọdun naa ni. Yaba lo ti kọkọ kawe alakọọbẹrẹ, lẹyin naa lo tun ka ni Warri, ko too waa lọ si ileewe giga Methodist Boys High School ni ilu Eko, nibi to ti ka iwe mẹwaa rẹ jade. Odun 1959 lo wọ iṣẹ awọn ologun, to si kọṣẹ ṣọja ni Ghana ati niluu oyinbo, ni Sandhurst, lo ba di ọọfisa kekere. O wa ninu awọn ti wọn jagun ni Congo, bẹẹ lo si di awọn ileeṣẹ ologun mi-in mu nigba to ti Congo de. Ọmọ ọgbọn ọdun geere lo wa ninu oṣu keji ọdun 1966 nigba to gba oye Mejọ, ọdun kan lẹyin iyẹn lo si di gomina ipinlẹ Eko. Ọdun mẹjọ geere lo fi ṣe gomina, nitori ni 1975 ti Muratala Muhammed gbajọba kuro lọwọ Yakubu Gowon ni wọn ni ki oun naa fẹyin ti ninu iṣẹ ologun, o si ti di Birigedia ki wọn too ni ko maa rele. O wa ninu akọsilẹ pe nigba ti awọn Muritala de, ti wọn ni ki wọn maa wadii awọn gomina to kowo jẹ labẹ ijọba Gowon, awọn gomina meji pere ni wọn ko ka ẹru ofin mọ lọwọ, Mobọlaji Johnson si jẹ ọkan ninu wọn. Lati igba to ti fẹyin ti naa lo ti n ran gbogbo awọn gomina to ba jẹ lekoo lọwọ, iriri to ni lo fi n kọ gbogbo wọn. Ṣugbọn iku ti ja a gba bayii, o tun di bi ẹni n jọni, bi eeyan n jọọyan; o di arinnako, o di oju ala, ka too tun ri ẹni bii Mobọlaji Johnson laarin wa. Ọrun rere o, Mobọlaji Johnson, ọga awọn jagunjagun odi gberee.
0 Comments
Post a Comment